Habakkuk 2

Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn wòlíì Habakuku

1 aÈmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye
Èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre
Èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi
àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.

Ìdáhùn Olúwa

2Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé:

“Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
3 bNítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
kí yóò sìsọ èké.
Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”


4 c“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga;
Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.
5Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,

“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
7Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
8Nítorí ìwọ ti kó orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀
Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.

9“Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
10Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ
11Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

12“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
13Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná
kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?
14Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
bí omi ti bo Òkun.

15“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,
kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn”
16Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn,
ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,
ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
17Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀
Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;
ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

18“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
ère dídá ti ń kọ ni èké?
Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;
ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
19Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘di alààyè?’
Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’
Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?
Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká;
kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”

20 dṢùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.
Copyright information for YorBMYO